Native Bible

Acts 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn.

Acts 6:8 in English

Acts 6:8 · Berean Standard Bible

Now Stephen, who was full of grace and power, was performing great wonders and signs among the people.

Context

6Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn. 7Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà. 8Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn. 9Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn, 10ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.