Ìṣe àwọn Aposteli 4:7
Acts 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”
Acts 4:7 in English
Acts 4:7 · Berean Standard Bible
They had Peter and John brought in and began to question them: “By what power or what name did you do this?”
Context
5Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu. 6Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà. 7Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?” 8Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn! 9Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.