Native Bible

Acts 4:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí.

Acts 4:16 in English

Acts 4:16 · Berean Standard Bible

“What shall we do with these men?” they asked. “It is clear to everyone living in Jerusalem that a remarkable miracle has occurred through them, and we cannot deny it.

Context

14Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbèrò. 16Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí. 17Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.” 18Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.