Ìṣe àwọn Aposteli 3:16
Acts 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.
Acts 3:16 in English
Acts 3:16 · Berean Standard Bible
By faith in the name of Jesus, this man whom you see and know has been made strong. It is Jesus’ name and the faith that comes through Him that has given him this complete healing in your presence.
Context
14Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣẹ́ Ẹni Mímọ́ àti Olóòótọ́ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín. 15Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́. 16Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín. 17“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe. 18Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.