Ìṣe àwọn Aposteli 28:3
Acts 28:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.
Acts 28:3 in English
Acts 28:3 · Berean Standard Bible
Paul gathered a bundle of sticks, and as he laid them on the fire, a viper, driven out by the heat, fastened itself to his hand.
Context
1Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà. 2Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa. Nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù. 3Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. 4Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.” 5Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.