Ìṣe àwọn Aposteli 28:20
Acts 28:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Israẹli ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”
Acts 28:20 in English
Acts 28:20 · Berean Standard Bible
So for this reason I have called to see you and speak with you. It is because of the hope of Israel that I am bound with this chain.”
Context
18Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi. 19Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Kesari, kì í ṣe pe mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi. 20Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Israẹli ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.” 21Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Judea nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ. 22Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ẹgbẹ́ ìlànà yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.