Native Bible

Acts 27:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni.

Acts 27:7 in English

Acts 27:7 · Berean Standard Bible

After sailing slowly for many days, we arrived off Cnidus. When the wind impeded us, we sailed to the lee of Crete, opposite Salmone.

Context

5Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti Pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia. 6Níbẹ̀ ni balógun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-òkun Alekisandiria kan, ti ń lọ sí Itali; ó sì fi wa sínú rẹ̀. 7Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni. 8Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Lasea. 9Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.