Native Bible

Acts 27:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Acts 27:3 in English

Acts 27:3 · Berean Standard Bible

The next day we landed at Sidon, and Julius treated Paul with consideration, allowing him to visit his friends and receive their care.

Context

1Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu. 2Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa. 3Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 4Nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, a lọ lẹ́bàá Saipurọsi, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì. 5Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti Pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.