Ìṣe àwọn Aposteli 27:22
Acts 27:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀.
Acts 27:22 in English
Acts 27:22 · Berean Standard Bible
But now I urge you to keep up your courage, because you will not experience any loss of life, but only of the ship.
Context
20Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́. 21Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa. 22Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀. 23Nítorí angẹli Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná. 24Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari. Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.