Native Bible

Acts 27:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀.

Acts 27:18 in English

Acts 27:18 · Berean Standard Bible

We were tossed so violently that the next day the men began to jettison the cargo.

Context

16Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò. 17Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri. 18Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀. 19Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù. 20Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.