Native Bible

Acts 27:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ.

Acts 27:15 in English

Acts 27:15 · Berean Standard Bible

Unable to head into the wind, the ship was caught up. So we gave way and let ourselves be driven along.

Context

13Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ. 14Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà. 15Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ. 16Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò. 17Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.