Native Bible

Acts 27:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.”

Acts 27:10 in English

Acts 27:10 · Berean Standard Bible

“Men, I can see that our voyage will be filled with disaster and great loss, not only to ship and cargo, but to our own lives as well.”

Context

8Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Lasea. 9Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn. 10Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.” 11Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ̀ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Paulu wí lọ. 12Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fonike, tí i ṣe èbúté Krete ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oòrùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oòrùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.