Native Bible

Acts 25:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”

Acts 25:9 in English

Acts 25:9 · Berean Standard Bible

But Festus, wishing to do the Jews a favor, said to Paul, “Are you willing to go up to Jerusalem to stand trial before me on these charges?”

Context

7Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. 8Paulu si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹmpili, tàbí sí Kesari.” 9Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?” 10Paulu sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kesari níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú. 11Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí ó ṣe pe mo sì ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú, ṣùgbọ́n bí kò bá sí òtítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fi ọ̀ràn mi lọ Kesari.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.