Native Bible

Acts 25:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Festu sì wí pé, “Agrippa ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ béèrè lọ́wọ́ mi ni Jerusalẹmu àti Kesarea níhìn-ín yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láààyè mọ́.

Acts 25:24 in English

Acts 25:24 · Berean Standard Bible

Then Festus said, “King Agrippa and all who are present with us, you see this man. The whole Jewish community has petitioned me about him, both here and in Jerusalem, crying out that he ought not to live any longer.

Context

22Agrippa wí fún Festu pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkára mi.” Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.” 23Ní ọjọ́ kejì, tí Agrippa àti Bernike wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀ṣọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Festu pàṣẹ, wọ́n sì mú Paulu jáde. 24Festu sì wí pé, “Agrippa ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ béèrè lọ́wọ́ mi ni Jerusalẹmu àti Kesarea níhìn-ín yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láààyè mọ́. 25Ṣùgbọ́n èmi rí i pe, kò ṣe ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkára rẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Augustu, mo tí pinnu láti rán an lọ. 26Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá síwájú yín, àní síwájú rẹ ọba Agrippa, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí ṣe ìwádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.