Native Bible

Acts 24:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Paulu yóò mú owó ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun ba à lè dá a sílẹ̀, nítorí náà a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkígbà, a máa bá a sọ̀rọ̀.

Acts 24:26 in English

Acts 24:26 · Berean Standard Bible

At the same time, he was hoping that Paul would offer him a bribe. So he sent for Paul frequently and talked with him.

Context

24Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Feliksi pẹ̀lú Drusilla ìyàwó rẹ̀ dé, obìnrin tí í ṣe Júù. Ó ránṣẹ́ pé Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 25Bí Paulu sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Feliksi, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsin yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.” 26Ní àkókò yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Paulu yóò mú owó ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun ba à lè dá a sílẹ̀, nítorí náà a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkígbà, a máa bá a sọ̀rọ̀. 27Lẹ́yìn ọdún méjì, Porkiu Festu rọ́pò Feliksi, Feliksi sì ń fẹ́ ṣe ojúrere fún àwọn Júù, ó fi Paulu sílẹ̀ nínú túbú. 24.6 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ pé, ṣùgbọ́n àwa gbá a mú àwa sí fẹ́ bá a ṣe ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin wa. 7 Ṣùgbọ́n Lisia olórí ogun dé, ó fì agbára ńlá gbà á lọ́wọ́ wa, 8 ó sì pàṣẹ pé kí àwọn olùfisùn rè wá sí iwájú rẹ. Nígbà

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.