Ìṣe àwọn Aposteli 24:23
Acts 24:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó máa ṣe ìtọ́jú Paulu, kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kun láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Acts 24:23 in English
Acts 24:23 · Berean Standard Bible
He ordered the centurion to keep Paul under guard, but to allow him some freedom and permit his friends to minister to his needs.
Context
21Bí kò ṣe tí gbólóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ síta nígbà tí mo dúró láàrín wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín ló ni yìí!’ ” 22Nígbà tí Feliksi gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, òye sá à ye é ní àyétán nípa ọ̀nà náà; ó tú wọn ká ná, ó ní, “Nígbà tí Lisia olórí ogun bá sọ̀kalẹ̀ wá, èmi ó wádìí ọ̀ràn yín dájú.” 23Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó máa ṣe ìtọ́jú Paulu, kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kun láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un. 24Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Feliksi pẹ̀lú Drusilla ìyàwó rẹ̀ dé, obìnrin tí í ṣe Júù. Ó ránṣẹ́ pé Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 25Bí Paulu sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Feliksi, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsin yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.