Native Bible

Acts 24:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn nínú tẹmpili, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú Sinagọgu tàbí ní ibikíbi nínú ìlú.

Acts 24:12 in English

Acts 24:12 · Berean Standard Bible

Yet my accusers did not find me debating with anyone in the temple or riling up a crowd in the synagogues or in the city.

Context

10Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Paulu sì dáhùn wí pe, “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀tayọ̀ wí tí ẹnu mi. 11Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerusalẹmu láti lọ jọ́sìn. 12Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn nínú tẹmpili, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú Sinagọgu tàbí ní ibikíbi nínú ìlú. 13Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsin yìí. 14Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀lé ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.