Ìṣe àwọn Aposteli 22:18
Acts 22:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kánkán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’
Acts 22:18 in English
Acts 22:18 · Berean Standard Bible
and saw the Lord * saying to me, ‘Hurry! Leave Jerusalem quickly, because the people here will not accept your testimony about Me.’
Context
16Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitiisi rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pe orúkọ rẹ̀.’ 17“Nígbà tí mo padà wá sí Jerusalẹmu tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹmpili, mo bọ́ sí ojúran, 18mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kánkán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’ 19“Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú Sinagọgu kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́. 20Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Stefanu ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń ṣe ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.