Native Bible

Acts 21:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun.

Acts 21:34 in English

Acts 21:34 · Berean Standard Bible

Some in the crowd were shouting one thing, and some another. And since the commander could not get at the truth because of the uproar, he ordered that Paul be brought into the barracks.

Context

32Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu. 33Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. 34Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. 35Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. 36Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.