Native Bible

Acts 21:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀.

Acts 21:3 in English

Acts 21:3 · Berean Standard Bible

After sighting Cyprus and passing south of it, we sailed on to Syria and landed at Tyre, where the ship was to unload its cargo.

Context

1Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, à si gba ibẹ̀ lọ sí Patara, 2A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. 3Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. 4Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. 5Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.