Native Bible

Acts 21:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.”

Acts 21:13 in English

Acts 21:13 · Berean Standard Bible

Then Paul answered, “Why are you weeping and breaking my heart? I am ready not only to be bound, but also to die in Jerusalem for the name of the Lord Jesus.”

Context

11Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí, ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ” 12Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!” 15Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.