Ìṣe àwọn Aposteli 20:10
Acts 20:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.”
Acts 20:10 in English
Acts 20:10 · Berean Standard Bible
But Paul went down, threw himself on the young man, and embraced him. “Do not be alarmed!” he said. “He is still alive!”
Context
8Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. 9Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. 10Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” 11Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.