Ìṣe àwọn Aposteli 19:15
Acts 19:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”
Acts 19:15 in English
Acts 19:15 · Berean Standard Bible
Eventually, one of the evil spirits answered them, “Jesus I know, and I know about Paul, but who are you?”
Context
13Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.” 14Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù. 15Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?” 16Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa. 17Ìròyìn yìí sì di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Giriki pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Efesu; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jesu Olúwa ga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.