Ìṣe àwọn Aposteli 18:5
Acts 18:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà.
Acts 18:5 in English
Acts 18:5 · Berean Standard Bible
And when Silas and Timothy came down from Macedonia, Paul devoted himself fully to the word, testifying to the Jews that Jesus is the Christ.
Context
3Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn. 4Ó sì ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú Sinagọgu lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Giriki lọ́kàn padà. 5Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà. 6Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn mi mọ́: láti ìsinsin yìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.” 7Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ọkùnrin kan tí a ń pé ní Titu Justu, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sinagọgu tímọ́tímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.