Ìṣe àwọn Aposteli 18:24
Acts 18:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Júù kan sì wà tí a ń pè ni Apollo, tí a bí ni Alekisandiria, ó wá sí Efesu. Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀.
Acts 18:24 in English
Acts 18:24 · Berean Standard Bible
Meanwhile a Jew named Apollos, a native of Alexandria, came to Ephesus. He was an eloquent man, well versed in the Scriptures.
Context
22Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Kesarea, ó gòkè lọ si Jerusalẹmu láti kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Antioku. 23Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀, ó n lọ, láti káàkiri ni agbègbè Galatia àti Frigia, o ń mu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le. 24Júù kan sì wà tí a ń pè ni Apollo, tí a bí ni Alekisandiria, ó wá sí Efesu. Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀. 25Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu dáradára; kìkì bamitiisi tí Johanu ní ó mọ̀. 26Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sinagọgu. Nígbà tí Akuila àti Priskilla gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀, wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.