Native Bible

Acts 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Efesu, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀.

Acts 18:19 in English

Acts 18:19 · Berean Standard Bible

When they reached Ephesus, Paul parted ways with Priscilla and Aquila. He himself went into the synagogue there and reasoned with the Jews.

Context

17Gbogbo àwọn Giriki sì mú Sostene, olórí Sinagọgu, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gallioni kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí. 18Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea, nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́. 19Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Efesu, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀. 20Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀. 21Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì lọ kúrò láti Efesu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.