Ìṣe àwọn Aposteli 17:22
Acts 17:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Acts 17:22 in English
Acts 17:22 · Berean Standard Bible
Then Paul stood up in the meeting * of the Areopagus and said, “Men of Athens, I see that in every way you are very religious.
Context
20Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá sí etí wa, àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.” 21Nítorí gbogbo àwọn ará Ateni, àti àwọn àjèjì tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí kí a máa gbọ́ ohun tuntun lọ. 22Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 23Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:
Fún Ọlọ́run àìmọ̀.
Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin. 24“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.