Native Bible

Acts 17:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Epikure ni àti tí àwọn Stoiki kó tì í. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí oníwàásù àjèjì òrìṣà, wọ́n sọ èyí nítorí Paulu ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu àti àjíǹde fún wọn.”

Acts 17:18 in English

Acts 17:18 · Berean Standard Bible

Some Epicurean and Stoic philosophers also began to debate with him. Some of them asked, “What is this babbler trying to say?” Others said, “He seems to be advocating foreign gods.” They said this because Paul was proclaiming the good news of Jesus and the resurrection.

Context

16Nígbà tí Paulu dúró dè wọ́n ni Ateni, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà. 17Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sinagọgu, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́. 18Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Epikure ni àti tí àwọn Stoiki kó tì í. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí oníwàásù àjèjì òrìṣà, wọ́n sọ èyí nítorí Paulu ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu àti àjíǹde fún wọn.” 19Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Areopagu, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ tuntun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? 20Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá sí etí wa, àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.