Ìṣe àwọn Aposteli 16:34
Acts 16:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.
Acts 16:34 in English
Acts 16:34 · Berean Standard Bible
Then he brought them into his home and set a meal before them. So he and all his household rejoiced that they had come to believe in God.
Context
32Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. 33Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a sì bamitiisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà. 34Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́. 35Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídàájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.” 36Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Paulu, wí pé, “Àwọn onídàájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da ìwọ àti Sila sílẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.