Native Bible

Acts 16:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀.

Acts 16:26 in English

Acts 16:26 · Berean Standard Bible

Suddenly a strong earthquake shook the foundations of the prison. At once all the doors flew open and everyone’s chains came loose.

Context

24Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀. 25Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run, àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. 26Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀. 27Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣe bí àwọn ara túbú ti sálọ. 28Ṣùgbọ́n Paulu gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má ṣe pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn-ín yìí!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.