Ìṣe àwọn Aposteli 15:2
Acts 15:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.
Acts 15:2 in English
Acts 15:2 · Berean Standard Bible
And after engaging these men in sharp debate, Paul and Barnabas were appointed, along with some other believers, to go up to Jerusalem to see the apostles and elders about this question.
Context
1Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.” 2Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí. 3Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà, wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin. 4Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.