Ìṣe àwọn Aposteli 13:34
Acts 13:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
Acts 13:34 in English
Acts 13:34 · Berean Standard Bible
In fact, God raised Him from the dead, never to see decay. As He has said: ‘I will give you the holy and sure blessings promised to David.’*
Context
32“Àwa sì mú ìyìnrere wá fún yín pé, ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde, bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé,
“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
lónìí ni mo bí ọ.’ 34Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:
“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’ 35Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé,
“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’ 36“Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.