Native Bible

Acts 12:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n.

Acts 12:16 in English

Acts 12:16 · Berean Standard Bible

But Peter kept on knocking, and when they opened the door and saw him, they were astounded.

Context

14Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 15Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!” 16Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. 17Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé, “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn. 18Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.