Ìṣe àwọn Aposteli 12:13
Acts 12:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn.
Acts 12:13 in English
Acts 12:13 · Berean Standard Bible
He knocked at the outer gate, and a servant girl named Rhoda came to answer it.
Context
11Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!” 12Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. 13Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. 14Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 15Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.