Native Bible

Acts 11:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi.

Acts 11:5 in English

Acts 11:5 · Berean Standard Bible

“I was in the city of Joppa praying, and in a trance I saw a vision of something like a large sheet being let down from heaven by its four corners, and it came right down to me.

Context

3wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.” 4Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé, 5“Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi. 6Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko igbó, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 7Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Peteru: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.