Ìṣe àwọn Aposteli 11:22
Acts 11:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku;
Acts 11:22 in English
Acts 11:22 · Berean Standard Bible
When news of this reached the ears of the church in Jerusalem, they sent Barnabas to Antioch.
Context
20Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. 21Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa. 22Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; 23Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. 24Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.