Native Bible

Acts 11:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”

Acts 11:18 in English

Acts 11:18 · Berean Standard Bible

When they heard this, their objections were put to rest, and they glorified God, saying, “So then, God has granted even the Gentiles repentance unto life.”

Context

16Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’ 17Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?” 18Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!” 19Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. 20Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.