Ìṣe àwọn Aposteli 10:42
Acts 10:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú.
Acts 10:42 in English
Acts 10:42 · Berean Standard Bible
And He commanded us to preach to the people and to testify that He is the One appointed by God to judge the living and the dead.
Context
40Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. 41Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. 42Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. 43Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.” 44Bí Peteru sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.