Ìṣe àwọn Aposteli 10:29
Acts 10:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi, ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”
Acts 10:29 in English
Acts 10:29 · Berean Standard Bible
So when I was invited, I came without objection. I ask, then, why have you sent for me?”
Context
27Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ. 28Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́. 29Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi, ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?” 30Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi. 31Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.