Native Bible

Acts 10:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.

Acts 10:19 in English

Acts 10:19 · Berean Standard Bible

As Peter continued to reflect on the vision, the Spirit said to him, “Behold, three men are looking for you.*

Context

17Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 18Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀. 19Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ. 20Ǹjẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kó ara ró láti bá wọn lọ, nítorí èmi ni ó rán wọn.” 21Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá, kín ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi wá?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.