Native Bible

Acts 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín; ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”

Acts 1:8 in English

Acts 1:8 · Berean Standard Bible

But you will receive power when the Holy Spirit comes upon you, and you will be My witnesses in Jerusalem, and in all Judea and Samaria, and to the ends of the earth.”

Context

6Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?” 7Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. 8Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín; ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” 9Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn. 10Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.