Native Bible

Acts 1:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”

Acts 1:5 in English

Acts 1:5 · Berean Standard Bible

For John baptized with water, but in a few days you will be baptized with the Holy Spirit.*”

Context

3Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. 4Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn, “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. 5Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.” 6Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?” 7Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.