2 Timotiu 4:3
2 Timothy 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.
2 Timothy 4:3 in English
2 Timothy 4:3 · Berean Standard Bible
For the time will come when men will not tolerate sound doctrine, but with itching ears they will gather around themselves teachers to suit their own desires.
Context
1Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. 2Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. 3Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. 4Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. 5Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.