2 Timotiu 4:14
2 Timothy 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
2 Timothy 4:14 in English
2 Timothy 4:14 · Berean Standard Bible
Alexander the coppersmith did great harm to me. The Lord will repay him according to his deeds.
Context
12Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu. 13Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ. 14Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. 15Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀. 16Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀, àdúrà mi ni kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.