Native Bible

2 Timothy 2:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù.

2 Timothy 2:24 in English

2 Timothy 2:24 · Berean Standard Bible

And a servant of the Lord must not be quarrelsome, but must be kind to everyone, able to teach, and forbearing.

Context

22Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe, sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá. 23Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀. 24Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù. 25Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́, 26wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdẹ̀kùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.