2 Timotiu 2:21
2 Timothy 2:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.
2 Timothy 2:21 in English
2 Timothy 2:21 · Berean Standard Bible
So if anyone cleanses himself of what is unfit,* he will be a vessel for honor: sanctified, useful to the Master, and prepared for every good work.
Context
19Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúrò nínú àìṣòdodo.” 20Ṣùgbọ́n nínú ilé ńlá, kì í ṣe kìkì ohun èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá. 21Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo. 22Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe, sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá. 23Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.