Native Bible

2 Timothy 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run.

2 Timothy 2:16 in English

2 Timothy 2:16 · Berean Standard Bible

But avoid irreverent, empty chatter, which will only lead to more ungodliness,

Context

14Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ. 16Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run. 17Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Filetu wà; 18àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.