Native Bible

2 Timothy 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi.

2 Timothy 1:6 in English

2 Timothy 1:6 · Berean Standard Bible

For this reason I remind you to fan into flame the gift of God, which is in you through the laying on of my hands.

Context

4Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀. 5Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú. 6Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. 7Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro. 8Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.