Native Bible

2 Thessalonians 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

2 Thessalonians 3:16 in English

2 Thessalonians 3:16 · Berean Standard Bible

Now may the Lord of peace Himself give you peace at all times and in every way. The Lord be with all of you.

Context

14Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa òfin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ sàmì sí ẹni náà. Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í. 15Síbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀tá, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí arákùnrin yín. 16Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. 17Èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe àmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí. 18Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.