Native Bible

2 Thessalonians 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará,

2 Thessalonians 2:1 in English

2 Thessalonians 2:1 · Berean Standard Bible

Now concerning the coming of our Lord Jesus Christ and our being gathered together to Him, we ask you, brothers,

Context

1Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará, 2kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná. 3Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.